Genesis 6:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kan òrùlé sí orí ọkọ̀ náà, ṣugbọn fi ààyè sílẹ̀ láàrin orí rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ yíká, tí yóo jẹ́ ìwọ̀n igbọnwọ kan. Kí o kan ọkọ̀ náà ní ìpele mẹta, kí o sì ṣe ẹnu ọ̀nà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ferese ni iwọ o si ṣe si ọkọ̀ na ni igbọ́nwọ kan ni ki iwọ ki o si pari wọn loke; lẹgbẹ ni iwọ o si dá ẹnu-ọ̀na ọkọ̀ na, si: pẹlu yara isalẹ, atẹle, ati ẹkẹta loke ni iwọ o ṣe e.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣe òrùlé sí orí ọkọ̀ náà ní ìgbọ̀nwọ́ kan, sì ṣe ọkọ̀ náà ní alájà mẹ́ta, ipá kan ní ìṣàlẹ̀, ọ̀kan ní àárin àti ọ̀kan tí ó kù ní òkè, ẹ̀gbẹ́ ni kí ó ṣe ẹnu ọ̀nà ọkọ̀ náà sí.