Genesis 6:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí o sì mú meji meji ninu gbogbo ohun alààyè, kí wọ́n lè wà láàyè pẹlu rẹ, takọ-tabo ni kí o mú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati ninu ẹdá alãye gbogbo, ninu onirũru ẹran, meji meji ninu gbogbo ẹran ni iwọ o mu wọ̀ inu ọkọ̀ na, lati mu nwọn là pẹlu rẹ; ti akọ ti abo ni ki nwọn ki o jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò mú gbogbo ohun alààyè takọ tabo wá sí inú ọkọ̀ kí wọn le wà láàyè pẹ̀lú rẹ.