Genesis 6:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Meji meji yóo tọ̀ ọ́ wá ninu oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ, ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹran ọ̀sìn, ati oríṣìíríṣìí àwọn ohun tí ń fàyà fà lórí ilẹ̀, kí o lè mú kí wọ́n wà láàyè pẹlu rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu ẹiyẹ nipa irú ti wọn, ninu ẹran-ọ̀sin nipa irú ti wọn, ninu ohun gbogbo ti nrakò ni ilẹ nipa irú tirẹ̀, meji meji ninu gbogbo wọn ni yio ma tọ̀ ọ wá lati mu wọn wà lãye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mú onírúurú àwọn ẹyẹ, ẹranko àti àwọn ohun tí ń rákò ní méjìméjì kí a bá lè pa wọ́n mọ́ láàyè.