Genesis 6:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá wí pé, “N kò ní jẹ́ kí eniyan wà láàyè títí lae, nítorí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n. Ọgọfa (120) ọdún ni wọn yóo máa gbé láyé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si wipe, Ẹmi mi ki yio fi igba-gbogbo ba enia jà, ẹran-ara sa li on pẹlu: ọjọ́ rẹ̀ yio si jẹ ọgọfa ọdún.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni OLÚWA wí pé, “Èémí ìyè tí mo mí sínú ènìyàn kò ní máa gbé inú ènìyàn títí láé, nítorí ẹran ara ṣáà ni òun, ọgọ́fà ọdún, ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”