Genesis 9:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí òṣùmàrè bá yọ, n óo wò ó, n óo sì ranti majẹmu ayérayé tí èmi Ọlọrun bá gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ó wà láyé dá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Òṣumare na yio si wà li awọsanma; emi o si ma wò o, ki emi le ma ranti majẹmu lailai ti o wà pẹlu Ọlọrun ati gbogbo ọkàn alãye ti o wà ninu gbogbo ẹdá ti o wà li aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbàkígbà tí òsùmàrè bá yọ ní ojú ọ̀run, èmi yóò rí i, èmi yóò sì rántí májẹ̀mú ayérayé tí ń bẹ láàrin Ọlọ́run àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tí ń bẹ ní ayé.”