Genesis 9:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣemu ati Jafẹti bá mú aṣọ kan, wọ́n fà á kọ́ èjìká wọn, wọ́n fi ẹ̀yìn rìn lọ sí ibi tí baba wọn sùn sí, wọ́n sì dà á bò ó, wọ́n kọ ojú sí ẹ̀gbẹ́ kan, wọn kò sì rí ìhòòhò baba wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati Ṣemu ati Jafeti mu gọgọwu, nwọn si fi le ejika awọn mejeji, nwọn si fi ẹhin rìn, nwọn si bò ìhoho baba wọn; oju wọn si wà lẹhin; nwọn kò si ri ìhoho baba wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Ṣémù àti Jáfétì mú aṣọ lé èjìká wọn, wọ́n sì fi ẹ̀yìn rìn, wọ́n sì bo ìhòòhò baba wọn. Wọ́n kọjú ṣẹ́yìn kí wọn kí ó má ba à rí ìhòòhò baba wọn.