Genesis 9:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹnikẹ́ni tí ó bá paniyan, pípa ni a óo pa òun náà, nítorí pé ní àwòrán Ọlọrun fúnrarẹ̀ ni ó dá eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnikẹni ti o ba ta ẹ̀jẹ enia silẹ, lati ọwọ́ enia li a o si ta ẹ̀jẹ rẹ̀ silẹ: nitoripe li aworan Ọlọrun li o dá enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀ láti ọwọ́ ènìyàn ni a ó gbà ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Nítorí ní àwòrán Ọlọ́run ni Ọlọ́run dá ènìyàn.