Habakkuk 1:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mímọ́ ni ojú rẹ, o kò lè wo ibi o kò lè gba ohun tí kò tọ́. Kí ló wá dé tí o fi ń wo àwọn ọ̀dàlẹ̀, tí o sì dákẹ́, tí ò ń wo àwọn ẹni ibi níran tí wọn ń run àwọn tí wọ́n ṣe olódodo jù wọ́n lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oju rẹ mọ́ jù ẹniti iwò ibi lọ, iwọ kò si lè wò ìwa-ìka: nitori kini iwọ ha ṣe nwò awọn ti nhùwa arekerekè, ti o si pa ẹnu rẹ mọ, nigbati ẹni-buburu jẹ ẹniti iṣe olododo jù u run?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi; ìwọ kò le gbà ìwà ìkà nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láàyè? Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa ẹni tí i ṣe olododo ju wọn lọ run?