Habakkuk 1:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà a máa bọ àwọ̀n rẹ̀. A sì máa fi turari rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀ ńlá; nítorí a máa rò lọ́kàn rẹ̀ pé, àwọ̀n òun ni ó ń jẹ́ kí òun gbádùn ayé tí òun sì fi ń rí oúnjẹ aládùn jẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, nwọn nrubọ si àwọn wọn, nwọn si nsùn turari fun awò wọn; nitori nipa wọn ni ipin wọn ṣe li ọrá, ti onjẹ wọn si fi di pupọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ó rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀, ó sì ń ṣun tùràrí fún àwọ̀n-ńlá rẹ̀ nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fí ń gbé ní ìgbádùn tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.