Habakkuk 1:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọlọrun ní: “Wo ààrin àwọn orílẹ̀-èdè yíká, O óo rí ohun ìjọjú yóo sì yà ọ́ lẹ́nu. Nítorí mò ń ṣe nǹkan ìyanu kan ní àkókò rẹ, tí o kò ní gbàgbọ́ bí wọ́n bá sọ fún ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ wò inu awọn keferi, ki ẹ si wò o, ki hà ki o si ṣe nyin gidigidi: nitoriti emi o ṣe iṣẹ kan li ọjọ nyin, ti ẹ kì yio si gbagbọ́, bi a tilẹ sọ fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ wo ìnú àwọn aláìkọlà, ki ẹ sí wòye, Kí ìyàlẹnu kí o sí ṣe yin gidigidi Nítorí tí èmi yóò ṣe ohun kan ni òwúrọ̀ ọjọ́ ọ yín tí ẹ̀yin kì yóò sì gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé a sọ fún un yin.