Habakkuk 2:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ibi tí ó dé bá Lẹbanoni yóo bò yín mọ́lẹ̀; ìparun àwọn ẹranko yóo dẹ́rùbà yín, nítorí ìpànìyàn ati ibi tí ẹ ṣe sí ayé, sí àwọn ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti ìwa-ipá ti Lebanoni yio bò ọ, ati ikogun awọn ẹranko, ti o bà wọn li ẹ̀ru, nitori ẹjẹ̀ enia, ati ìwa ipá ilẹ na, ti ilu na, ati ti gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ìwà-ipá tí ó tí hù sí Lébánónì yóò bò ọ́, àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́. Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.