Habakkuk 2:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èrè kí ni ó wà ninu ère? Ère irin lásánlàsàn, tí eniyan ṣe, tí ń kọ́ni ní irọ́ pípa. Nítorí ẹni tí ó ṣe wọ́n gbẹ́kẹ̀lé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ère tí ó gbẹ́ tán tí kò lè sọ̀rọ̀!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Erè kini ere fínfin nì, ti oniṣọna rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ; ere didà, ati olùkọ eké, ti ẹniti nṣe iṣẹ rẹ̀ fi gbẹkẹ̀le e, lati ma ṣe ere ti o yadi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ, ère dídá àti olùkọ́ èké? Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnrarẹ̀ dá; ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.