Habakkuk 2:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ǹjẹ́ gbogbo àwọn eniyan wọnyi kò ní máa kẹ́gàn rẹ̀, kí wọ́n sì máa fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ń kó ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ jọ. Ìgbà wo ni yóo ṣe èyí dà, tí yóo máa gba ìdógò lọ́wọ́ àwọn onígbèsè rẹ̀ kiri?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo awọn wọnyi kì yio ma pa owe si i, ti nwọn o si ma kọ orin owe si i, wipe, Egbe ni fun ẹniti nmu ohun ti kì iṣe tirẹ̀ pọ̀ si i! yio ti pẹ to? ati fun ẹniti ndi ẹrẹ̀ ilọnilọwọgbà ru ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Gbogbo àwọn wọ̀nyí kì yóò máa pa òwe sí i tí wọn yóò sì máa kọ orin òwe sí i wí pé, “ ‘Ègbé ni fún ẹni tí ń mu ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ pọ̀ sí i! Tí ó sì ṣọ ara rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ nípaṣẹ̀ ìlọ́nilọ́wọ́ gbà! Eléyìí yóò ha ti pẹ́ tó?’