Habakkuk 2:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ǹjẹ́ àwọn onígbèsè rẹ kò ní dìde sí ọ lójijì, kí àwọn tí wọn yóo dẹ́rùbà ọ́ sì jí dìde, kí o wá di ìkógun fún wọn?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ti o yọ ọ lẹnu, kì yio ha dide lojiji? awọn ti o wahalà rẹ kì yio ha ji? iwọ kì yio ha si di ikogun fun wọn?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ ẹni ti ó yọ ọ́ lẹ́nu, kí yóò ha dìde lójijì? Àti àwọn tí ó wàhálà rẹ kì yóò ha jí ni bi? Nígbà náà ni ìwọ yóò wa dí ìkógun fún wọn.