Habakkuk 2:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni o ti kó lẹ́rú, gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọn yóo sì kó ìwọ náà lẹ́rú, nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan tí o ti pa, ati ìwà ipá tí o hù lórí ilẹ̀ ayé, ati èyí tí o hù sí oríṣìíríṣìí ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori iwọ ti kó orilẹ-ède pupọ̀, gbogbo iyokù awọn enia na ni yio kó ọ; nitori ẹjẹ̀ enia, ati ìwa-ipá ilẹ na, ti ilu na, ati ti gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ìwọ tí ko orílẹ̀-èdè púpọ̀, àwọn ènìyàn tó kù yóò sì kó ọ nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀; nítorí ẹ̀jẹ̀ Ìwọ tí pa ilẹ̀ àti ìlú ńlá run àti gbogbo ènìyàn to ń gbé inú rẹ̀.