Habakkuk 3:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
O fi ọ̀kọ̀ rẹ gún orí àwọn olórí ogun; àwọn tí wọ́n wá bí ìjì líle láti tú wa ká, tí wọn ń yọ̀ bí ẹni tí ń ni talaka lára níkọ̀kọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ ti fi ọ̀pa rẹ̀ lu awọn olori iletò rẹ̀ já: nwọn rọ́ jade bi ãjà lati tu mi ka: ayọ̀ wọn ni bi ati jẹ talakà run nikọ̀kọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀ kí ó fi gún orí rẹ nígbà tí àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde láti tú wá ká: ayọ̀ wọn sì ni láti jẹ talákà run ní kọ̀kọ̀.