Habakkuk 3:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo gbọ́, àyà mi sì lù kìkì, ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nígbà tí mo gbọ́ ìró rẹ̀; egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí rà, ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì nílẹ̀. N óo fi sùúrù dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ tí ìṣòro yóo dé bá àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati mo gbọ́, ikùn mi warìri; etè mi gbọ̀n li ohùn na; ibàjẹ wọ̀ inu egungun mi lọ, mo si warìri ni inu mi, ki emi ba le simi li ọjọ ipọnju: nigbati o ba goke tọ̀ awọn enia lọ, yio ke wọn kuro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì, ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà; ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ, ẹ̀sẹ̀ mi sì wárìrì, mo dúró ni ìdákẹ́jẹ́ fún ọjọ́ ìdààmú láti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.