Habakkuk 3:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA, mo ti gbọ́ òkìkí rẹ, mo sì bẹ̀rù iṣẹ́ ọwọ́ rẹ. Gbogbo bí ò ó tíí ṣe tí à ń gbọ́; tún wá ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tiwa; sì ranti àánú ní àkókò ibinu rẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa, mo ti gbọ́ ohùn rẹ, ẹ̀ru si bà mi: Oluwa, mu iṣẹ rẹ sọji lãrin ọdun, lãrin ọdun sọ wọn di mimọ̀; ni ibinu ranti ãnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA mo tí gbọ́ ohùn rẹ; ẹrú sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ OLÚWA ṣọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa, ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mímọ̀; ni ìbínú, rántí àánú.