Habakkuk 3:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA, ṣé àwọn odò ni inú rẹ ń ru sí ni, àbí àwọn ìṣàn omi ni ò ń bínú sí, tabi òkun ni ò ń bá bínú, nígbà tí o bá gun àwọn ẹṣin rẹ, tí o wà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa ha binu si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si awọn odò? ibinu rẹ̀ ha wà si okun, ti iwọ fi ngùn ẹṣin rẹ ati kẹkẹ́ igbàla rẹ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn Odò nì, OLÚWA? Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò síṣàn bí? Ìbínú rẹ ha wá sórí òkun tí ìwọ fi ń gún ẹṣin, àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlá rẹ?