Haggai 1:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ni Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli ati Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa, ati gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù bá gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun wọn lẹ́nu, wọ́n fetí sí ọ̀rọ̀ wolii Hagai, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun wọn ti rán an; wọ́n sì bẹ̀rù OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, ati Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, pẹlu gbogbo enia iyokù, gba ohùn Oluwa Ọlọrun wọn gbọ́, ati ọ̀rọ Hagai woli, gẹgẹ bi Oluwa Ọlọrun wọn ti rán a, awọn enia si bẹ̀ru niwaju Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Sérúbábélì ọmọ Séítíélì, Jósúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ìyókù, gba ohùn OLÚWA Ọlọ́run wọn gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wòlíì Hágáì, nítorí OLÚWA Ọlọ́run ni ó rán an. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù OLÚWA.