Haggai 1:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA bá fi ìtara rẹ̀ sí ọkàn Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, gomina ilẹ̀ Juda, ati sí ọkàn Joṣua ọmọ Jehosadaki, olórí alufaa ati ọkàn gbogbo àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa si rú ẹ̀mi Serubbabeli ọmọ Ṣealtieli, bãlẹ Juda soke, ati ẹmi Joṣua ọmọ Josedeki, olori alufa, ati ẹmi gbogbo awọn enia iyokù; nwọn si wá nwọn si ṣiṣẹ ni ile Oluwa awọn ọmọ-ogun Ọlọrun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, OLÚWA ru ẹ̀mí Sérúbábẹ́lì ọmọ Séítélì sókè, olórí Júdà àti ẹ̀mí Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn,