Haggai 1:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ̀ ń retí ọ̀pọ̀ ìkórè, ṣugbọn díẹ̀ ni ẹ̀ ń rí; nígbà tí ẹ sì mú díẹ̀ náà wálé, èmi á gbọ̀n ọ́n dànù. Mò ń bi yín, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tí ó fà á? Ìdí rẹ̀ ni pé, ẹ fi ilé mi sílẹ̀ ní òkítì àlàpà, olukuluku sì múra sí kíkọ́ ilé tirẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin tí nreti ọ̀pọ, ṣugbọn kiyesi i, diẹ ni; nigbati ẹnyin si mu u wá ile, mo si fẹ ẹ danù. Nitori kini? li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi. Nitori ti ile mi ti o dahoro; ti olukuluku nyin si nsare fun ile ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsíi,, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dáhoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀.