Haggai 2:12 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ǹjẹ́ bí ẹnìkan bá mú ẹran tí a fi rúbọ, tí ó ti di mímọ́, tí ó dì í mọ́ ìṣẹ́tí ẹ̀wù rẹ̀, tí ó sì fi ẹ̀wù náà kan burẹdi, tabi àsáró, tabi waini, tabi òróró, tabi oúnjẹ-kóúnjẹ, ṣé ọ̀kan kan ninu àwọn oúnjẹ yìí lè tipa bẹ́ẹ̀ di mímọ́?” Àwọn alufaa bá dáhùn pé, “Rárá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ẹnikan ba rù ẹran mimọ́ ni iṣẹti aṣọ rẹ̀, ti o si fi iṣẹti aṣọ rẹ̀ kan àkara, tabi àṣaró, tabi ọti-waini, tabi ororo, tabi ẹrankẹran, yio ha jẹ mimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Bẹ̃kọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan Búrẹ́dì tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’ ” Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.”