Haggai 2:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kò sí ọkà ninu abà mọ, igi àjàrà ati igi ọ̀pọ̀tọ́ kò sì tíì so; bẹ́ẹ̀ ni igi pomegiranate, ati igi olifi. Ṣugbọn láti òní lọ, n óo bukun yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eso ha wà ninu abà bi? lõtọ, àjara, ati igi òpọtọ, ati pomegranate, ati igi olifi, kò iti so sibẹ̀sibẹ̀: lati oni lọ li emi o bukún fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ èso ha wà nínú abà bí? Títí di àkókò yìí, àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ àti pómégíránátè, àti igi ólífì kò ì tíì so èso kankan. “ ‘Láti òní lọ ni èmi yóò bùkún fún-un yin.’ ”