Haggai 2:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo lé àwọn ìjọba kúrò ní ipò wọn; n óo sì ṣẹ́ àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè lápá. N óo ta kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n lókìtì. Ẹṣin ati àwọn tí wọn ń gùn wọ́n yóo ṣubú, wọn óo sì fi idà pa ara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si bì itẹ awọn ijọba ṣubu, emi o si pa agbara ijọba keferi run; emi o si doju awọn kẹkẹ́ de, ati awọn ti o gùn wọn; ati ẹṣin ati awọn ẹlẹṣin yio wá ilẹ; olukuluku nipa idà arakunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, Èmi yóò sì pa agbára àwọn aláìkọlà run; Èmi yóò sì dojú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun dé, àti àwọn tí ń gùn wọ́n; ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́sin yóò ṣubú; olúkúlùkù nípa idà arákùnrin rẹ̀.”