Haggai 2:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ náà, n óo fi ìwọ Serubabeli, ọmọ Ṣealitieli, ṣe aṣojú ninu ìjọba mi nítorí pé mo ti yàn ọ́. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o mu ọ, Iwọ Serubbabeli, iranṣẹ mi, ọmọ Ṣealtieli, li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di oruka edídi kan: nitoriti mo ti yàn ọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA àwọn wí pé, “Ní ọjọ́ náà, àwọn ọmọ-ogun iwọ ìránṣẹ́ mi Sérúbábélì ọmọ Séítíélì, Èmi yóò mú ọ, Èmi yóò sì sọ ọ di bí òrùka èdìdì mi, nítorí mo ti yan ọ, ni OLÚWA àwọn ọmọ-ogun wí.”