Haggai 2:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
‘Àwọn wo ni wọ́n ṣẹ́kù ninu yín tí wọ́n rí i bí ẹwà ògo ilé yìí ti pọ̀ tó tẹ́lẹ̀? Báwo ni ẹ ti rí i sí nisinsinyii? Ǹjẹ́ ó jẹ́ nǹkankan lójú yín?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tali o kù ninu nyin ti o ti ri ile yi li ogo rẹ̀ akọṣe? bawo li ẹnyin si ti ri i si nisisiyi? kò ha dàbi asan loju nyin bi a fi ṣe akawe rẹ̀?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Ta ni nínú yín tí ó kù tí ó sì ti rí ilé yìí ní ògo rẹ̀ àkọ́kọ́? Báwo ni ó ṣe ri sí yín nísinsin yìí? Ǹjẹ́ kò dàbí asán lójú yín?