Hebrews 1:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọmọ yìí jẹ́ ẹni tí ògo Ọlọrun hàn lára rẹ̀, ó sì jẹ́ àwòrán bí Ọlọrun ti rí gan-an. Òun ni ó mú kí gbogbo nǹkan dúró nípa agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó ti wẹ ẹ̀ṣẹ̀ eniyan nù tán, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọ̀gá Ògo ní ibi tí ó ga jùlọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti iṣe itanṣan ogo rẹ̀, ati aworan on tikararẹ, ti o si nfi ọ̀rọ agbara rẹ̀ mu ohun gbogbo duro, lẹhin ti o ti ṣe ìwẹnu ẹ̀ṣẹ, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlánla li oke;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọmọ tí í ṣe ìtànsán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkálárarẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró: Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ọlá-ńlá ní òkè.