Hebrews 10:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí Òfin Mose jẹ́ òjìji àwọn ohun rere tí ń bọ̀, kì í ṣe àwòrán wọn gan-an. Òfin ṣe ìlànà nípa irú ẹbọ kan náà tí àwọn eniyan yóo máa rú lọdọọdun. Ṣugbọn òfin kò lè sọ àwọn tí ń wá siwaju Ọlọrun di pípé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NITORI ofin bi o ti ni ojiji awọn ohun rere ti mbọ̀ laijẹ aworan pãpã awọn nkan na, nwọn kò le fi ẹbọ kanna ti nwọn nru nigbagbogbo li ọdọ̃dún mu awọn ti nwá sibẹ̀ di pipé.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí òfin, bí o ti ní òjìjì àwọn ohun rere ti ń bẹ̀ tí kì í ṣe àwòrán tóòtọ́ fún rere nǹkan náà, kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbàgbogbo lọdọ́ọ̀dún mu àwọn tí ń wá sibẹ̀ di pípé.