Hebrews 10:34 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni ẹ bá àwọn ẹlẹ́wọ̀n jìyà. Pẹlu ayọ̀ ni ẹ fi gbà kí wọ́n fi agbára kó àwọn dúkìá yín lọ, nítorí ẹ mọ̀ pé ẹ ní dúkìá tí ó tún dára ju èyí tí wọn kó lọ, tí yóo sì pẹ́ jù wọ́n lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ẹnyin bá awọn ti o wà ninu ìde kẹdun, ẹ si fi ayọ̀ gbà ìkolọ ẹrù nyin, nitori ẹnyin mọ̀ ninu ara nyin pe, ẹ ni ọrọ̀ ti o wà titi, ti o si dara ju bẹ̃ lọ li ọ̀run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ẹ̀yin bá àwọn tí ó wà nínú ìdè kẹ́dùn, ẹ sì fi ayọ̀ gba ìkólọ ẹrù yin, nítorí ẹ̀yin mọ nínú ara yin pé, ẹ ni ọrọ̀ tí ó wà títí, tí ó sì dára jù bẹ́ẹ̀ lọ.