Hebrews 10:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní àkọ́kọ́ ó ní, “Kì í ṣe ẹbọ ati ọrẹ tabi ẹbọ sísun ati ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ ni o fẹ́, kì í ṣe àwọn ni inú rẹ dùn sí.” Àwọn ẹbọ tí wọn ń rú nìyí gẹ́gẹ́ bí ìlànà ti Òfin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o wi ni iṣaju pe, Iwọ kò fẹ ẹbọ ati ọrẹ, ati ẹbọ sisun, ati ẹbọ fun ẹ̀ṣẹ, bẹ̃ni iwọ kò ni inu didun si wọn (awọn eyiti a nrú gẹgẹ bi ofin).
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí o wí ni ìṣáajú pé, “Ìwọ kò fẹ́ ẹbọ àti ọ̀rẹ àti ẹbọ sísun, àti ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò ni inú dídùn si wọn” (àwọn èyí tí a ń rú gẹ́gẹ́ bí òfin).