Hebrews 11:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ó tó àkókò tí Josẹfu yóo kú, nípa igbagbọ ni ó fi ranti pé àwọn ọmọ Israẹli yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì sọ bí òun ti fẹ́ kí wọ́n ṣe egungun òun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nipa igbagbọ́ ni Josefu, nigbati o nkú lọ, o ranti ìjadelọ awọn ọmọ Israeli; o si paṣẹ niti awọn egungun rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nípa ìgbàgbọ́ ni Jósẹ́fù, nígbà tí ó ń ku lọ, ó rántí ìjáde lọ àwọn ọmọ Ísraẹ́lì; ó sì pàṣẹ níti àwọn egungun rẹ̀.