Hebrews 12:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NITORINA bi a ti fi awọsanmọ ti o kún to bayi fun awọn ẹlẹri yí wa ká, ẹ jẹ ki a pa ohun idiwọ gbogbo tì si apakan, ati ẹ̀ṣẹ ti o rọrun lati dì mọ wa, ki a si mã fi sũru sure ije ti a gbé ka iwaju wa,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà bí a ti fi ikúukùu àwọsánmà tí o kún fún àwọn ẹlẹ́ri tó báyìí yí wa ká, ẹ jẹ́ kí a pa ohun ìdíwọ́ gbogbo tí si apákan, àti ẹ̀ṣẹ̀ tí o rọrùn láti di mọ́ wa, kí a sì máa fi sùúrù súré ìje tí a gbé ka iwájú wa,