Hebrews 12:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kíyèsára kí ẹ má ṣàì bìkítà fún ẹni tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé nígbà tí àwọn tí wọ́n ṣàì bìkítà fún Ọlọrun nígbà tí ó rán Mose ní iṣẹ́ sí ayé kò bọ́ lọ́wọ́ ìyà, báwo ni àwa ṣe le bọ́ bí a bá ṣàì bìkítà fún ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kiyesi i, ki ẹ máṣe kọ̀ ẹniti nkilọ. Nitori bi awọn wọnni kò ba bọ́ nigbati nwọn kọ̀ ẹniti nkilọ li aiye, melomelo li awa kì yio bọ́ awa ti o pẹhinda si ẹniti nkilọ lati ọrun wá:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kíyèsí i, kí ẹ má ṣe kọ̀ ẹni tí ń kìlọ̀. Nítorí bí àwọn wọ̀nyí kò bá bọ́ nígbà tí wọn kọ̀ ẹni ti ń kìlọ̀ ni ayé, mélomélo ni àwa kì yóò bọ́, bí àwa ba pẹ̀hìndè sí ẹni tí ń kìlọ̀ láti ọ̀run wá: