Hebrews 13:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ohun tí ó lọ́lá ni igbeyawo. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì yẹ kí gbogbo yín kà á sí. Ibùsùn tọkọtaya gbọdọ̀ jẹ́ aláìléèérí. Nítorí Ọlọrun yóo dájọ́ fún àwọn oníṣekúṣe ati àwọn àgbèrè.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki igbéyawo ki o li ọla larin gbogbo enia, ki akete si jẹ alailẽri: nitori awọn àgbere ati awọn panṣaga li Ọlọrun yio dá lẹjọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrin gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléérí: Nítorí àwọn àgbérè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ̀jọ́.