Hebrews 2:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé kí Ọlọrun tí ó dá gbogbo nǹkan, tí ó sì mú kí gbogbo nǹkan wà, lè mú ọpọlọpọ wá sí inú ògo, ó tọ́ kí ó ṣe aṣaaju tí yóo la ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fún wọn nípa ìyà jíjẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe o yẹ fun u, nitori ẹniti ohun gbogbo ṣe wà, ati nipasẹ ẹniti ohun gbogbo wà, ni mimu awọn ọmọ pupọ̀ wá sinu ogo, lati ṣe balogun igbala wọn li aṣepé nipa ìjiya.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé ó yẹ fún Ọlọ́run, nítorí nípasẹ̀ ẹni tí ohun gbogbo ṣẹ̀ wà, láti mú àwọn ọmọ púpọ̀ wá sínú ògo, láti ṣe Balógun ìgbàlà wọn ni àṣepé nípa ìjìyà.