Hebrews 2:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
báwo ni a óo ti ṣe sá àsálà, tí a bá kọ etí-ikún sí ìgbàlà tí ó tóbi tó báyìí? Oluwa fúnrarẹ̀ ni ó kọ́kọ́ kéde ìgbàlà yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́ ni wọ́n fún wa ní ìdánilójú pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa o ti ṣe là a, bi awa kò ba nani irú igbala nla bi eyi; ti àtetekọ bẹ̀rẹ si isọ lati ọdọ Oluwa, ti a si fi mulẹ fun wa lati ọdọ awọn ẹniti o gbọ́;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
kí ni ohun náà tí ó mú wa lérò pé a lè bọ́ kúrò nínú ìjìyà bí a kò bá náání ìgbàlà ńlá yìí? Ìgbàlà tí Olúwa fúnraarẹ̀ kọ́kọ́ kéde, èyí tí a sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún wa láti ọwọ́ àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lẹ́nu rẹ̀.