Hebrews 2:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn a rí Jesu, tí Ọlọrun fi sí ipò tí ó rẹlẹ̀ díẹ̀ ju ti àwọn angẹli fún àkókò díẹ̀. Òun ni ó jẹ oró ikú, tí Ọlọrun tún wá fi ògo ati ọlá dé e ládé. Nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ó kú fún gbogbo eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa ri ẹniti a dá rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ, ani Jesu, ẹniti a fi ogo ati ọlá dé li ade nitori ijiya ikú; ki o le tọ́ iku wò fun olukuluku enia nipa õre-ọfẹ Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n àwa rí Jésù ẹni tí a rẹ̀ sílẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ańgẹ́lì lọ fún àkókò díẹ̀, àní Jésù, ẹni tí a fi ògo àti ọlá dé ní adé nítorí ìjìyà wa; kí ó lè tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.