Hebrews 3:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn Kristi ṣe olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ninu ìdílé rẹ̀. Àwa gan-an ni ìdílé rẹ̀ náà, bí a bá dúró pẹlu ìgboyà tí à ń ṣògo lórí ìrètí wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn Kristi bi ọmọ lori ile rẹ̀; ile ẹniti awa iṣe, bi awa ba dì igbẹkẹle ati iṣogo ireti wa mu ṣinṣin titi de opin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Kírísítì jẹ́ olóòtọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ lórí ilé Ọlọ́run; ilé ẹni tí àwá jẹ́, bí àwá bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tí a sì di ìṣògo ìrètí wa mu ṣinṣin títí dé òpin.