Hebrews 4:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà láàyè, ó sì lágbára. Ó mú ju idà olójú meji lọ. Ó mú tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi lè gé ẹ̀mí kúrò lára ọkàn, ó sì lè rẹ́ mùdùnmúdùn kúrò lára àwọn oríkèé ara. Ó yára láti mọ ète ati èrò ọkàn eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ọ̀rọ Ọlọrun yè, o si li agbara, o si mú jù idàkídà oloju meji lọ, o si ngúnni ani tìti de pipín ọkàn ati ẹmí niya, ati oríke ati ọrá inu egungun, on si ni olumọ̀ erò inu ati ète ọkàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ní agbára, ó sì mu ju idàkídà olójú-méjì lọ, ó sì ń gunni àní títí dé pínpín ọkàn àti ẹ̀mí níyà, àti ní oríkèé àti ọ̀rá inú egungun, òun sì ni olùmọ̀ èrò inú àti ète ọkàn.