Hebrews 4:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwa tí a gbàgbọ́ ni a wọ inú ìsinmi náà. Nígbà tí Ọlọrun sọ pé, “Mo búra pẹlu ibinu pé, wọn kò ní wọ inú ìsinmi mi.” Ó sọ bẹ́ẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti parí iṣẹ́ rẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe awa ti o ti gbagbọ́ wọ̀ inu isimi gẹgẹ bi o ti wi, Bi mo ti bura ninu ibinu mi, nwọn ki yio wọ̀ inu isimi mi: bi o tilẹ ti ṣe pe a ti pari iṣẹ wọnni lati ipilẹ aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí, “Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpilẹ̀ ayé.