Hebrews 5:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí ẹnikẹ́ni tí a bá yàn láàrin àwọn eniyan láti jẹ́ olórí alufaa, a yàn án bí aṣojú àwọn eniyan níwájú Ọlọrun, kí ó lè máa mú àwọn ọrẹ ati ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn wá siwaju Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NITORI olukuluku olori alufa ti a yàn ninu awọn enia, li a fi jẹ fun awọn enia niti ohun ti iṣe ti Ọlọrun, ki o le mã mu ẹ̀bun wá ati lati ṣe ẹbọ nitori ẹ̀ṣẹ:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí olórí àlùfáà kọ̀ọ̀kan tí a yàn nínú àwọn ènìyàn, ní a fi jẹ nítorí iṣẹ́ ìsìn àwọn ènìyàn sí Ọlọ́run láti máa mú ẹ̀bùn àti ẹbọ wá nítorí ẹ̀ṣẹ̀.