Hebrews 6:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọ̀nà kan náà, nígbà tí Ọlọrun fẹ́ fihàn gbangba fún àwọn ajogún ìlérí wí pé èrò òun kò yipada, ó ṣe ìlérí, ó sì fi ìbúra tì í.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu eyiti bi Ọlọrun ti nfẹ gidigidi lati fi aileyipada ìmọ rẹ̀ han fun awọn ajogún ileri, o fi ibura sãrin wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidgidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrin wọn.