Hebrews 6:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí nígbà tí ilẹ̀ bá ń mu omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà, tí ó sì ń mú kí ohun ọ̀gbìn hù fún àwọn àgbẹ̀ tí ń roko níbẹ̀, ilẹ̀ náà ń gba ibukun Ọlọrun ni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ilẹ ti o fi omi ojò ti nrọ̀ sori rẹ̀ nigbagbogbo mu, ti o si nhù ewebẹ ti o dara fun awọn ti a nti itori wọn ro o pẹlu, ngbà ibukún lọwọ Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hú ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run.