Hebrews 7:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí Mẹlikisẹdẹki yìí jẹ́ ọba Salẹmu ati alufaa Ọlọrun Ọ̀gá Ògo. Òun ni ó pàdé Abrahamu nígbà tí Abrahamu ń pada bọ̀ láti ojú-ogun lẹ́yìn tí ó bá ọba mẹrin jà, tí ó sì pa wọ́n ní ìpakúpa. Ó bá súre fún Abrahamu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NITORI Melkisedeki yi, ọba Salemu, alufa Ọlọrun Ọgá-ogo, ẹniti o pade Abrahamu bi o ti npada lati ibi pipa awọn ọba bọ̀, ti o si sure fun u;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí Melikisédékì yìí, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run ọ̀gá ògo, ẹni tí ó pàdé Ábúráhámù bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un.