Hebrews 7:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé ètò iṣẹ́ alufaa ti ìdílé Lefi kò ní àbùkù, tí ó sì jẹ́ pé nípa rẹ̀ ni àwọn eniyan fi gba òfin, kí ló dé tí a fi tún ṣe ètò alufaa ní ìgbésẹ̀ Mẹlikisẹdẹki, tí kò fi jẹ́ ti Aaroni?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ ibaṣepe pipé mbẹ nipa oyè alufa Lefi, (nitoripe labẹ rẹ̀ li awọn enia gbà ofin), kili o si tún kù mọ́ ti alufa miran iba fi dide nipa ẹsẹ Melkisedeki, ti a kò si wipe nipa ẹsẹ Aaroni?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Léfì, (nítorí pé lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn gba òfin), kínni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melikísédékì, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Árọ́nì?