Hebrews 7:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Òun kì í ṣe ẹni tí ó níláti kọ́kọ́ rúbọ lojoojumọ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀, kí ó tó wá rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan, bí àwọn olórí alufaa ti ìdílé Lefi ti ń ṣe. Nítorí lẹ́ẹ̀kan náà ni ó ti ṣe èyí, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹniti kò ni lati mã kọ́ rubọ lojojumọ, bi awọn olori alufa wọnni, fun ẹ̀ṣẹ ti ara rẹ̀ na, ati lẹhinna fun ti awọn enia: nitori eyi li o ti ṣe lẹ̃kanṣoṣo, nigbati o fi ara rẹ̀ rubọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí kò ní láti máa rúbọ lójojúmọ́, bí àwọn olórí àlùfáà, fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ náà, àti lẹ̀yìn náà fún tí àwọn ènìyàn; nítorí èyí ni tí ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ.