Hebrews 7:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kò sí àkọsílẹ̀ pé ó ní baba tabi ìyá; kò ní ìtàn ìdílé. Kò sí àkọsílẹ̀ ìbẹ̀rẹ̀ tabi òpin ìgbé-ayé rẹ̀. Ó jẹ́ àwòrán Ọmọ Ọlọrun. Ó jẹ́ alufaa nígbà gbogbo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Laini baba, laini iyá, laini ìtan iran, bẹ̃ni kò ni ibẹrẹ ọjọ tabi opin ọjọ aiye; ṣugbọn a ṣe e bi Ọmọ Ọlọrun; o wà li alufa titi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láínì baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bí ọmọ Ọlọ́run; ó wà ní àlùfáà títí.