Hebrews 7:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ Lefi ni wọ́n ní àṣẹ láti gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin. Wọ́n ń gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn eniyan wọn tí wọ́n jẹ́ ìran Abrahamu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nitõtọ awọn ti iṣe ọmọ Lefi, ti o gbà oyè alufa, nwọn ni aṣẹ lati mã gbà idamẹwa lọwọ awọn enia gẹgẹ bi ofin, eyini ni, lọwọ awọn arakunrin wọn, bi o tilẹ ti jẹ pe, nwọn ti inu Abrahamu jade.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Léfì, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Ábúráhámù jáde.