Hebrews 8:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Èyí ni majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tí ó bá yá. N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo kọ ọ́ sí ọkàn wọn, èmi óo jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà yóo sì jẹ́ eniyan mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori eyi ni majẹmu ti emi ó ba ile Israeli da lẹhin ọjọ wọnni, li Oluwa wi; Emi ó fi ofin mi si inu wọn, emi o si kọ wọn si ọkàn wọn: emi o si mã jẹ́ Ọlọrun fun wọn, nwọn o si mã jẹ́ enia fun mi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ̀yìn àwọn ọjọ́ wọ̀nyí, ni Olúwa wí. Èmi ó fi òfin mi sí inú wọn, èmi ó sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn, èmi ó sì máa jẹ́ Ọlọ́run fún wọn, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn fún mi.